1 Corinthians 12:12-14

12 aAra jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan ṣoṣo. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kristi tí í ṣe ìjọ. 13 bNítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitiisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá à ṣe Júù, ìbá à ṣe Giriki, ìbá à ṣe ẹrú, ìbá à ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 14Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀.

Copyright information for YorBMYO