Isaiah 14:29-31

29 aMá ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia,
pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;
láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀
yóò ti hù jáde,
èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.
30Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko,
àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu.
Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun,
yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.

31Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, Ìwọ ìlú!
Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia!
Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá,
kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.
Copyright information for YorBMYO