Psalms 46
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin. 1Ọlọ́run ni ààbò àti agbára waó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
2Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
3Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.
4Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
5Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
6Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.
7 Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.
8Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
9O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.
10Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè,
a ó gbé mi ga ní ayé.
11 Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa;
Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.
Copyright information for
YorYCB